Die Übersetzung in Yoruba - Abu Rahimah Mikail
Übersetzung der Bedeutungen des Edlen Korans
Übersetzt von Schaykh Abu Rahimah Mikail Aykyuni.
أَلَمۡ نَشۡرَحۡ لَكَ صَدۡرَكَ
Ṣé A kò ṣípayá igbá-àyà rẹ fún ọ bí?
وَوَضَعۡنَا عَنكَ وِزۡرَكَ
A sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò lọ́rùn rẹ,
ٱلَّذِيٓ أَنقَضَ ظَهۡرَكَ
èyí tí ó wọ̀ ọ́ lọ́rùn.[1]
وَرَفَعۡنَا لَكَ ذِكۡرَكَ
A sì gbé ìrántí orúkọ rẹ ga fún ọ.
فَإِنَّ مَعَ ٱلۡعُسۡرِ يُسۡرًا
Nítorí náà, dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira.
إِنَّ مَعَ ٱلۡعُسۡرِ يُسۡرٗا
Dájúdájú ìdẹ̀kùn wà lẹ́yìn ìnira sẹ́.
فَإِذَا فَرَغۡتَ فَٱنصَبۡ
Nítorí náà, nígbà tí o bá bùṣe (lórí ohun tí ó jẹmọ́ táyé), gbìyànjú (dáadáa lórí ìjọ́sìn).
وَإِلَىٰ رَبِّكَ فَٱرۡغَب
Ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sì ni kí o ṣojú kòkòrò oore sí.
share_via