یوربایي ژباړه
یوربا ژبې ته د قرآن کریم د معناګانو ژباړه، ژباړوونکی: الشیخ ابو رحیمة میکائیل ایکوییني. چاپ کال ۱۴۳۲ هـ.
قُلۡ هُوَ ٱللَّهُ أَحَدٌ
Sọ pé: “Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo.
Sọ pé: “Òun ni Allāhu, Ọ̀kan ṣoṣo.
ٱللَّهُ ٱلصَّمَدُ
Allāhu ni Aṣíwájú tí ẹ̀dá ní bùkátà sí níbi jíjọ́sìn fún Un àti títọrọ oore ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí Òun kò sì ní bùkátà sí wọn ní ọ̀nà kan kan.
Allāhu ni Aṣíwájú tí ẹ̀dá ní bùkátà sí níbi jíjọ́sìn fún Un àti títọrọ oore ní ọ̀dọ̀ Rẹ̀, tí Òun kò sì ní bùkátà sí wọn ní ọ̀nà kan kan.
لَمۡ يَلِدۡ وَلَمۡ يُولَدۡ
Kò bímọ. Wọn kò sì bí I.
Kò bímọ. Wọn kò sì bí I.
وَلَمۡ يَكُن لَّهُۥ كُفُوًا أَحَدُۢ
Kò sì sí ẹnì kan kan tí ó jọ Ọ́.”¹
1. Ẹ kíyè sí i! Àwọn kan máa ń ké “Ƙul huwa-llāhu” mẹ́ta fún òkú mùsùlùmí. Nígbà mìíràn, wọ́n lè ké òdidi al-Ƙur’ān fún un. Ìwọ̀nyí kò tọ sunnah rárá. Sūrah al-Haṣr; 59:10 ti fún wa ní àdúà tó jẹmọ́ òkú àti alààyè.
Síwájú sí i, ìtúmọ̀ “Ọlọ́hun” ni “Olúwa gbogbo ayé àti ọ̀run àti ohun tó wà láààrin méjèèjì”. Nínú èdè al-Ƙur’ān, èyí ni a mọ̀ sí “rọbbu-ssamọ̄wāt wal-’ard wa mọ̄ baenahumọ̄”. Ìdí nìyí tí a ò fi túmọ̀ “Allāhu” sí “Ọlọ́hun”. Nínú èdè Yorùbá, kò fẹ́ẹ̀ sí ìtúmọ̀ tí a fọkàn balẹ̀ sí fún ọ̀rọ̀-orúkọ ńlá náà “Allāhu” àfi lílo ọ̀rọ̀-orúkọ kan èyí tí àwọn Yorùbá máa ń lò ní ọjọ́un àná fún “Ọlọ́hun”. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ sí máa mú àríyànjiyàn lọ́wọ́. Nítorí náà, “Allāhu” ni “Allāhu”.
Kò sì sí ẹnì kan kan tí ó jọ Ọ́.”¹
مشاركة عبر